Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
A kì í gbọ́ ‘‘Lù ú’’ lẹ́nu àgbà.
1
Ikọ̀ ológun ti pinnu láti má ṣe sọ àbọ̀ ìpàdé wọn síta.
0
A-fi-tirẹ̀-sílẹ̀-gbọ́-tẹniẹlẹ́ni: Ọlọ́run ní ń ba gbọ́ tirẹ̀.
1
Arákùnrin náà sọ pé ẹni tí àwọn jọ wá ṣì ń sùn ní yàrá lọ́wọ́.
0
Bí a bá n yán gúgúrú elẹnu ńse la má ń súfèé tantan (bí bẹệ ko,yóó nìí a ti je e tán)
1
Èèyàn ìbáà kúrú, ìbáà búrẹ́wà, gbèsè ò sí, ìtìjú ò sí.
1
Atowọ ẹni, ď'ọwọ ẹni, l'ádìẹ bá dÓtù-Ufẹ.
1
Àkànbí kì í ṣe ẹnìkan tí ó máa ń fa ìjọ̀ngbọ̀n.
0
Bó-mọ-gín-ń-gín-ní-eegun-ní-ń lọ tí ń bá ọmọ-ọ rẹ̀ pín ìrẹ̀; Bó-mọ-jéḿpé-orí-ní ń tani tí ń bá baba-a rẹ̀ pín agbọ̀n rù.
1
‘‘Ojú ò f rakù’’ tó ta ajá ẹ̀ lókòó; ó ní bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ńtà á wọn a máa tún ara-a wọn rí.
1
A kì í téyín-ín ká, kí a máa fọwọ bò ó.
1
Èèyàn mẹ́ta, tó fi mọ́ ọmọ kékeré kan ni wọ́n há sí àárín àwọn ìdọ̀tí tó wà níbẹ̀.
0
Àjànàkú kúrò lẹ́ran à ń fajá dẹ.
1
Nínú oṣù karùn-ún ni wọn yóò gbé ìjọba kalẹ̀.
0
Wọ́n gbé Olúṣọlá lọ sí ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ní Ìlú Ògo.
0
Àwọn ologun náà ti ṣe ìjọba ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
0
Ààrẹ ń pè ọ́ ò ńdÍfá; bÍfá bá fọọre tí Ààrẹ́ fọbi ń kọ́?
1
Àgbà ló ń șèlú; ọmọdé ló ń seré-ale.
1
Àìná ṣubú lulẹ̀ nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ nígbà tí ọkọ rẹ̀ gún un pa.
0
Àjànàkú kì í sòpá kínú bí ọlọ́dẹ.
1
Ẹni a mọ kì í ru imọ.
1
Ènìyàn méjì tún jẹ́rìí sí ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì.
0
Ìbágbépọ̀ a máa mẹ́hẹ nígbà tí àjàkáyé-àrùn bá bẹ́ sílẹ̀.
0
Àgbẹ́kọ̀yà ní dùǹdú ìyà làwọn ṣọ́jà dín fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn.
0
Ó sọ pé láti alẹ́ ọjọ́ tí àwọn ti dé ilé ìtura ni olóògbé ti sọ pé ó rẹ òun.
0
Adébáyọ̀ ní ilé iṣẹ́ ìròyìn kan ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ọ̀gá ẹ̀ tún gbe lọ.
0
Àjàkálẹ̀ àrùn bẹ́ sílẹ̀ kárí àgbáyé.
0
Bí asọ́ bá pẹ́ lápò, á bu.
1
Débọ̀ ti sọ̀rọ̀sókè fún ìjọba Nàìjíríà lẹ́yìn tó ti àtìmọ́lé dé.
0
B'á a dárin l'ágbo tá ò rẹni (bá ni) gbèé janjan níí dun nì.
1
Wọ́n ti ṣe ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun mìíràn.
0
‘‘Ebí ńpa mí’’ ò ṣéé fìfé wí.
1
Afìkọ̀kọ̀jalè, bí ọba ayé ò rí ọ; tọ̀rún rí ọ.
1
Ètè l'ọkọ àróbọ; Ẹnu lọkoo korinkorin.
1
Gborí-gborí kì í gb'orí leệmejì.
1
Mo lọ sẹ́nu iṣẹ́ mi lẹ́yìn tí mo bẹ Tọ́pẹ́ láàrọ̀ ọjọ́ kejì.
0
Ìjàmbá ọkọ̀ ojú-irin wáyé láàárín Ẹlẹ́yẹlé sí Afàyàfà.
0
Àwọn afurasí kó igbó pamọ́ sínú àpò láti fi tan àwọn agbófinró jẹ.
0
Àfikún owó iná làti la ṣé dipo ìdajì tàwọn èèyàn n sọ́
0
Ẹfúnṣetán Aníwúrà jẹ ìyálóde Ìbàdàn nígbà kan, tó sì lówó.
0
Àti kékeré àjànàkú leerin-ín ti pọ̀ ju ẹfọ̀n lọ.
1
Àwọn ọmọ yìí nílò àmójútó gidi.
0
Àjòjì ní í jẹgbin ìlú.
1
Èèrà 'ò fẹ pòpóò dénú. Gínínngín lọmọ aráyé ń fẹnií mọ.
1
Ọdọọdún ni àyípadà ọ̀tun máa ń bá ẹ̀ka ìjọba tó ń ṣàkóso ìrìnnà ọkọ̀ òfurufú.
0
Bí ó bá ti pẹ tí Ìjesà ti jiyán, kì í tún mọ òkèléé bù mọ.
1
Ayọnil nu ọkùnrin ló ní òun ó jẹ ìrọ̀.
1
Àgbàlagbà tó wẹ̀wù àṣejù, ẹ̀tẹ́ ni yó fi rí.
1
Ewú wà nínú lílo ọmọ ogun láti kó àwọn ènìyàn kúrò.
0
Ení rìnrìn lẹlẹkùnlẹlẹkún ni wọn ń fi lẹkùn-ún mú leyìn-ęsę.
1
Ilé epò ẹ̀bá-ọ̀nà ti dáwọ́ títa epo dúró báyìí.
0
Ṣẹ́gun Adénúgà ṣàlàyé irú agbábọ́ọ̀lù tí Thunder jẹ́ lórí ọ̀dàn.
0
·Èèyàn jù q o ní die, sé o rí die náà rà lojà?
1
Ajàmọlàtán-fọwọ-nùpó 'ò mọyì ọbę.
1
Ààrẹ pàṣẹ láti kọlu jàǹdùkú, ọ̀daràn àti olè lórí afẹ́fẹ́.
0
Ọ̀gá ọlọ́pàá àgbà ti pàṣẹ pé kí wọ́n tari ọ̀daràn ọ̀hún sí ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́.
0
Eni tí 'ò mọséé je; èèmejì níí rìn.
1
Ẹnu nífá wà, ló dífá fún 'lwo èé wi?'
1
Mi ò rí ènìyàn tó dà bí ọ̀gá mi rí láyé.
0
Bí bá n dun nì, àyàmo pé ń dun ni. Ọrọ dun ni janjan l'àrankàn eni.
1
Àjókòó-ìfẹyìntì àgbàlagbà, bí ẹni nàró ló rí.
1
Bí ẹtu ò bá kú, ta ni yóò fi awọ-ọ rẹ̀ tọ́ ọsán? Bí ẹ̀kìrì ò bá kú, ta ni yóò fi awọ-ọ rẹ̀ dá bàtà? Bí olórìṣà ò bá kú, ta ni yóò gba ìbò-o rẹ̀ bò?
1
Ní gbogbo ìgbà ní olorì Aláàfin máa ń gbé àwòrán Òkìkíọlá síta.
0
Àwọn kan ń fi eré-ìdárayá gbọ́ bùkátà mọ̀lẹ́bí wọn.
0
Agbègbè Ìlúpéjú wà nílùú Èkó.
0
B'á a gb'ẹyin ș'ọwọ ọtún, káa gbẹyìn s'ọwọ òsì k'á a f'ęyìn; eyìn lọ dé Ìseyìn, eni tí 'ò ni yín ni 'ò ní yin ni.
1
Ọkùnrin náà pe àwọn aládùúgbò láti bá òun wo àwọn òbí òun nínú ilé.
0
Àwọn dẹrandẹran sọ iná sí oko àwọn àgbẹ̀ nì Ìlọrin.
0
Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà pé akíkanjú akọrin ni Àyìnlá Ọmọwúrà.
0
‘‘Gbà tọ́wò-ó’’ gbé ipọn mì; ‘‘Gbà ràn mí lẹ́rù-ú’’ di ẹlẹ́rù; ‘‘Bá mi gún èlùbọ́’’ fi ẹ̀gbẹ́ gún èèkàn.
1
A kì í bínú orí ká fi fìlà dé ìbàdí.
1
Bí a bá ṣe ohun ńlá, à fi èpè gba ara ẹni là.
1
Aì í wọ'lédì láì b'enikan so.
1
Àwọn kan ń fẹ́ kí Abíọ́dún di Ààre.
0
Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí máa ń gba owó ìrànwọ́ fuhn iwádìí ìjìnlẹ̀.
0
Bí ìtì ò wó, ọwọ́ kì í ba ìṣẹ́pẹ́ .
1
Arákùnrin kan fúnrarẹ̀ rìn lọ àgọ́ ọlọ́pàá.
0
Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ń hàn lábẹ́ aṣọ.
0
Ó dìgbà tí ìlú Ọ̀yọ́ bá ní Aláàfin kí wọ́n tó lè yan Lèmọ́mù tuntun.
0
Owó tí wọ́n gbà pọ̀ ju bí ilé ìfowópamọ́ ṣe lérò.
0
B'ísó ọmọ 'ò rùn, kí ti baba 'ę jáfíkán.
1
Ẹ jáwọ́ lórí ẹ̀sun Ṣòwòrẹ́: Adébáyọ̀ ló sọ èyí.
0
‘‘Gbọ́mọ wá kí mi,’’ owó ní ń náni.
1
Wọ́n ti fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún àwọn ọmọ ìyá méjì tí wọ́n jà ní ilé ìjọsìn.
0
Ẹbọ olówó kì í fu tálíkà.
1
Ilé alájà méjì dà wó ní ilé ìgbé àwọn ọlọ́pàá.
0
A kì í jà nígbó ráhùn ọpa.
1
Wọ́n fẹ́ yọ kíndìnrín ọmọkùnrin kan láti fi rọ́pò ti ọmọ wọn.
0
Bí a bá forí sọlẹ̀ tí a kò kú, ohun tí a ó ṣe-é kù.
1
Bí a ò bá tíì kúrò lódò, a kì í bú Ọnì, torí kó má baà gbé ni mì.
1
Àì í fẹnií kí ni “A ì í kí ni ìjẹta.'
1
Àjátì agbọn ní í kọ àparò lọgbọn.
1
Bí nǹkán bá tán nílẹ̀, ọmọ ẹbọ a bọ́ síjó, àwọn tó wà níbẹ̀ a múra àti lọ.
1
Bí a ò bá tó ọkọlóbìnrín-ín se; à ó șe elénìní ẹ.
1
B'ílùú 'ò tòrò, ọmọ tálíká ó leè ròde ẹmu.
1
Àwọn ènìyàn lọ bá Bàbá Ìjẹ̀bú yọ̀ ní ilé rẹ̀ tuntun.
0
‘‘Ó kún mi lójú,’’ ẹ̀kọ Arogun; ọ̀kan ṣoṣo ni mo rà, igba ènì ló fi sí i.
1
Àìsí nílé olórí orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ kí àwọn ènìyàn ìjọba ṣìwà hù..
0
Àsejù baba àsetę.
1
Kọmíṣọ́nà fọ́rọ̀ àwọn obìnrin sọ pé àwáwí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lásán ọ̀rọ̀ Ajíṣafẹ́.
0